Gbagede Otito
Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀.(Rm 8 : 28)
Dajudaju, kii se gbogbo eniyan ni ohun gbogbo nsise po fun rere fun, bikose awon to o fe Olorun , paapa julo awon ti a pe gegebi ipinnu Olorun..
Hmmmmm!!!!!!
Awon wo ni a pe gegebi ipinnu Olorun Olorun?
Awon ti won gba Jesu Kristi gbo ni.
Awon ti won si lee jewo Jesu Kristi lai fi igbagbo won pamo.
Awon wonyi ni ohun gbogbo nsise po fun rere fun nitori won fe Olorun won.
Jn 8:42, “Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe Ọlọrun ni Baba nyin, ẹnyin iba fẹran mi: nitoriti emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wá: bẹ̃li emi kò si wá fun ara mi, ṣugbọn on li o rán mi”
Nje iwo feran Re bi?
Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀.”(Jn 14:23)
Arakunrin, arabinrin, nje o fe ki Olorun maa ba o gbe bi?
Nje o fe ki Olorun di permanent resident ni ibugbe re?
Bi o ba fe bee; FERAN Olorun, PA ORO Re mo, nigba naa Oun pelu yio feran re ohun gbogbo yio si maa sise fun rere fun o. Amin.
Ojumo ire o.
Click here to claim your Sponsored Listing.
Category
Telephone
Website
Address
Ifo